8 Nwọn o si jẹ ẹran na ti a fi iná sun li oru na, ati àkara alaiwu; ewebẹ kikorò ni nwọn o fi jẹ ẹ.
9 Ẹ máṣe jẹ ninu rẹ̀ ni tutù, tabi ti a fi omi bọ̀, bikoṣepe sisun ninu iná; ati ori rẹ̀, ati itan rẹ̀, ati akopọ̀ inu rẹ̀ pẹlu.
10 Ẹ kò si gbọdọ jẹ ki nkan ki o kù silẹ ninu rẹ̀ dé ojumọ́; eyiti o ba si kù di ijọ́ keji on ni ki ẹnyin ki o daná sun.
11 Bayi li ẹnyin o si jẹ ẹ; ti ẹnyin ti àmure didì li ẹgbẹ nyin, bàta nyin li ẹsẹ̀ nyin, ati ọpá nyin li ọwọ́ nyin, ẹnyin o si yara jẹ ẹ: irekọja OLUWA ni.
12 Nitoriti emi o là ilẹ Egipti já li oru na, emi o si kọlù gbogbo awọn akọ́bi ni ilẹ Egipti, ti enia ati ti ẹran; ati lara gbogbo oriṣa Egipti li emi o ṣe idajọ: emi li OLUWA.
13 Ẹ̀jẹ na ni yio si ṣe àmi fun nyin lara ile ti ẹnyin gbé wà: nigbati emi ba ri ẹ̀jẹ na, emi o ré nyin kọja, iyọnu na ki yio wá sori nyin lati run nyin nigbati mo ba kọlù ilẹ Egipti.
14 Ọjọ́ oni ni yio si ma ṣe ọjọ́ iranti fun nyin, ẹnyin o si ma ṣe e li ajọ fun OLUWA ni iran-iran nyin, ẹ o si ma ṣe e li ajọ nipa ìlana lailai.