1 OLUWA si wi fun Mose pe,
2 Yà gbogbo awọn akọ́bi sọ̀tọ fun mi, gbogbo eyiti iṣe akọ́bi ninu awọn ọmọ Israeli, ati ti enia, ati ti ẹran: ti emi ni iṣe.
3 Mose si wi fun awọn enia na pe, Ẹ ranti ọjọ́ oni, ninu eyiti ẹnyin jade kuro ni Egipti, kuro li oko-ẹrú; nitori ọwọ́ agbara li OLUWA fi mú nyin jade kuro nihin: a ki yio si jẹ àkara wiwu.
4 Li ọjọ́ oni li ẹnyin jade li oṣù Abibu.
5 Yio si ṣe nigbati OLUWA yio mú ọ dé ilẹ awọn ara Kenaani, ati ti awọn enia Hitti, ati ti awọn ara Amori, ati awọn Hifi, ati awọn Jebusi, ti o ti bura fun awọn baba rẹ lati fi fun ọ, ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin, on ni iwọ o ma sìn ìsin yi li oṣù yi.
6 Ijọ́ meje ni iwọ o fi jẹ àkara alaiwu, li ọjọ́ keje li ajọ yio wà fun OLUWA.
7 Ọjọ́ meje li a o fi jẹ àkara alaiwu; ki a má si ṣe ri àkara wiwu lọdọ rẹ, bẹ̃ni ki a má si ṣe ri iwukàra lọdọ rẹ ni gbogbo ẹkùn rẹ.