18 Awọn ara Egipti yio si mọ̀ pe, emi li OLUWA, nigbati mo ba gbà ogo lori Farao, lori awọn kẹkẹ́ rẹ̀, ati lori awọn ẹlẹṣin rẹ̀.
19 Angeli Ọlọrun na ti o ṣaju ogun Israeli, o si ṣi lọ ṣẹhin wọn; ọwọ̀n awọsanma si ṣi kuro niwaju wọn, o si duro lẹhin wọn:
20 O si wá si agbedemeji ogun awọn ara Egipti ati ogun Israeli; o si ṣe awọsanma ati òkunkun fun awọn ti ọhún, ṣugbọn o ṣe imọlẹ li oru fun awọn ti ihin: bẹ̃li ekini kò sunmọ ekeji ni gbogbo oru na.
21 Mose si nà ọwọ́ rẹ̀ si oju okun; OLUWA si fi afẹfẹ lile ìla-õrùn mu okun bì sẹhin ni gbogbo oru na, o si mu okun gbẹ: omi na si pinya.
22 Awọn ọmọ Israeli si lọ sinu ãrin okun ni ilẹ gbigbẹ: omi si ṣe odi si wọn li ọwọ ọtún, ati ọwọ́ òsi.
23 Awọn ara Egipti si lepa wọn, nwọn si wọ̀ ọ tọ̀ wọn lọ lãrin okun, ati gbogbo ẹṣin Farao, ati kẹkẹ́ rẹ̀, ati awọn ẹlẹṣin rẹ̀.
24 O si ṣe, nigba iṣọ owurọ̀, OLUWA bojuwò ogun ara Egipti lãrin ọwọ̀n iná, ati ti awọsanma, o si pá ogun awọn ara Egipti làiya.