19 Angeli Ọlọrun na ti o ṣaju ogun Israeli, o si ṣi lọ ṣẹhin wọn; ọwọ̀n awọsanma si ṣi kuro niwaju wọn, o si duro lẹhin wọn:
20 O si wá si agbedemeji ogun awọn ara Egipti ati ogun Israeli; o si ṣe awọsanma ati òkunkun fun awọn ti ọhún, ṣugbọn o ṣe imọlẹ li oru fun awọn ti ihin: bẹ̃li ekini kò sunmọ ekeji ni gbogbo oru na.
21 Mose si nà ọwọ́ rẹ̀ si oju okun; OLUWA si fi afẹfẹ lile ìla-õrùn mu okun bì sẹhin ni gbogbo oru na, o si mu okun gbẹ: omi na si pinya.
22 Awọn ọmọ Israeli si lọ sinu ãrin okun ni ilẹ gbigbẹ: omi si ṣe odi si wọn li ọwọ ọtún, ati ọwọ́ òsi.
23 Awọn ara Egipti si lepa wọn, nwọn si wọ̀ ọ tọ̀ wọn lọ lãrin okun, ati gbogbo ẹṣin Farao, ati kẹkẹ́ rẹ̀, ati awọn ẹlẹṣin rẹ̀.
24 O si ṣe, nigba iṣọ owurọ̀, OLUWA bojuwò ogun ara Egipti lãrin ọwọ̀n iná, ati ti awọsanma, o si pá ogun awọn ara Egipti làiya.
25 O si yẹ̀ kẹkẹ́ wọn, nwọn si nwọ́ turu, awọn ara Egipti si wipe, Ẹ jẹ ki a sá kuro niwaju Israeli; nitoriti OLUWA mbá awọn ara Egipti jà fun wọn.