4 Emi o si mu àiya Farao le, ti yio fi lepa wọn; a o si yìn mi logo lori Farao, ati lori ogun rẹ̀ gbogbo; ki awọn ara Egipti ki o le mọ̀ pe, emi li OLUWA. Nwọn si ṣe bẹ̃.
5 A si wi fun ọba Egipti pe, awọn enia na sá: àiya Farao ati awọn iranṣẹ rẹ̀ si yi si awọn enia na, nwọn si wipe, Ẽṣe ti awa fi ṣe eyi, ti awa fi jẹ ki Israeli ki o lọ kuro ninu ìsin wa?
6 O si dì kẹkẹ́ rẹ̀, o si mú awọn enia rẹ̀ pẹlu rẹ̀.
7 O si mú ẹgbẹta ãyo kẹkẹ́, ati gbogbo kẹkẹ́ Egipti, ati olori si olukuluku wọn.
8 OLUWA si mu àiya Farao ọba Egipti le, o si lepa awọn ọmọ Israeli: ọwọ́ giga li awọn ọmọ Israeli si fi jade lọ.
9 Ṣugbọn awọn ara Egipti lepa wọn, gbogbo ẹṣin ati kẹkẹ́ Farao, ati awọn ẹlẹṣin rẹ̀, ati awọn ogun rẹ̀, o si lé wọn bá, nwọn duro li ẹba okun ni ìha Pi-hahirotu niwaju Baal-sefoni.
10 Nigbati Farao si nsunmọtosi, awọn ọmọ Israeli gbé oju soke, si kiyesi i, awọn ara Egipti mbọ̀ lẹhin wọn; ẹ̀ru si bà wọn gidigidi: awọn ọmọ Israeli si kigbe pè OLUWA.