1 ỌKUNRIN kan ara ile Lefi si lọ, o si fẹ́ ọmọbinrin Lefi kan.
2 Obinrin na si yún, o si bi ọmọkunrin kan: nigbati o si ri i pe, o ṣe ọmọ didara, o pa a mọ́ li oṣù mẹta.
3 Nigbati kò si le pa a mọ́ mọ́, o ṣe apoti ẽsu fun u, o si fi ọ̀da ilẹ ati oje igi ṣán a; o si tẹ́ ọmọ na sinu rẹ̀; o si gbé e sinu koriko odò li ẹba odò na.
4 Arabinrin rẹ̀ si duro li òkere, lati mọ̀ ohun ti yio ṣe ọmọ na.
5 Ọmọbinrin Farao si sọkalẹ wá lati wẹ̀ li odò; awọn ọmọbinrin ọdọ rẹ̀ si nrìn lọ li ẹba odò na; nigbati o si ri apoti na lãrin koriko odò, o rán ọmọbinrin ọdọ rẹ̀ kan lati lọ gbé e wá.
6 Nigbati o si ṣi i, o ri ọmọ na; si kiyesi i ọmọde na nsọkun. Inu rẹ̀ si yọ́ si i, o si wipe, Ọkan ninu awọn ọmọ Heberu li eyi.
7 Nigbana li arabinrin rẹ̀ wi fun ọmọbinrin Farao pe, Emi ka lọ ipè alagbatọ kan fun ọ wá ninu awọn obinrin Heberu, ki o tọ́ ọmọ na fun ọ?