14 Ṣugbọn bi enia ba ṣìka si aladugbo rẹ̀, lati fi ẹ̀tan pa a; ki iwọ ki o tilẹ mú u lati ibi pẹpẹ mi lọ, ki o le kú.
15 Ẹniti o ba si lù baba, tabi iya rẹ̀, pipa li a o pa a.
16 Ẹniti o ba si ji enia, ti o si tà a, tabi ti a ri i li ọwọ́ rẹ̀, pipa li a o pa a.
17 Ẹniti o ba si bú baba tabi iya rẹ̀, pipa li a o pa a.
18 Bi awọn ọkunrin ba si jùmọ̀ njà, ti ekini fi okuta lù ekeji, tabi ti o jìn i li ẹsẹ̀, ti on kò si kú ṣugbọn ti o da a bulẹ:
19 Bi o ba si tun dide, ti o ntẹ̀ ọpá rìn kiri ni ita, nigbana li ẹniti o lù u yio to bọ́; kìki gbèse akokò ti o sọnù ni yio san, on o si ṣe ati mu u lara da ṣaṣa.
20 Bi ẹnikan ba si fi ọpá lù ẹrú rẹ̀ ọkunrin tabi obinrin, ti o si kú si i li ọwọ́, a o gbẹsan rẹ̀ nitõtọ.