20 Bi ẹnikan ba si fi ọpá lù ẹrú rẹ̀ ọkunrin tabi obinrin, ti o si kú si i li ọwọ́, a o gbẹsan rẹ̀ nitõtọ.
21 Ṣugbọn bi o ba duro di ijọ́ kan, tabi meji, a ki yio gbẹsan rẹ̀: nitoripe owo rẹ̀ ni iṣe.
22 Bi awọn ọkunrin ba njà, ti nwọn si pa obinrin aboyún lara, tobẹ̃ ti oyún rẹ̀ ṣẹ́, ṣugbọn ti ibi miran kò si pẹlu: a o mu ki o san nitõtọ, gẹgẹ bi ọkọ obinrin na yio ti dá lé e; on o si san a niwaju onidajọ.
23 Bi ibi kan ba si pẹlu, njẹ ki iwọ ki o fi ẹmi dipò ẹmi.
24 Fi oju dipò oju, ehín dipò ehín, ọwọ́ dipò ọwọ́, ẹsẹ̀ dipò ẹsẹ̀.
25 Fi ijóna dipò ijóna, ọgbẹ́, dipò ọgbẹ́, ìna dipò ìna.
26 Bi o ba ṣepe ẹnikan ba lù ẹrú rẹ̀ ọkunrin tabi ẹrú rẹ̀ obinrin li oju ti o si fọ́; ki o si jọwọ rẹ̀ lọ li omnira nitori oju rẹ̀.