21 Ṣugbọn bi o ba duro di ijọ́ kan, tabi meji, a ki yio gbẹsan rẹ̀: nitoripe owo rẹ̀ ni iṣe.
22 Bi awọn ọkunrin ba njà, ti nwọn si pa obinrin aboyún lara, tobẹ̃ ti oyún rẹ̀ ṣẹ́, ṣugbọn ti ibi miran kò si pẹlu: a o mu ki o san nitõtọ, gẹgẹ bi ọkọ obinrin na yio ti dá lé e; on o si san a niwaju onidajọ.
23 Bi ibi kan ba si pẹlu, njẹ ki iwọ ki o fi ẹmi dipò ẹmi.
24 Fi oju dipò oju, ehín dipò ehín, ọwọ́ dipò ọwọ́, ẹsẹ̀ dipò ẹsẹ̀.
25 Fi ijóna dipò ijóna, ọgbẹ́, dipò ọgbẹ́, ìna dipò ìna.
26 Bi o ba ṣepe ẹnikan ba lù ẹrú rẹ̀ ọkunrin tabi ẹrú rẹ̀ obinrin li oju ti o si fọ́; ki o si jọwọ rẹ̀ lọ li omnira nitori oju rẹ̀.
27 Bi o ba si ká ehín ẹrú rẹ̀ ọkunrin, tabi ehín ẹrú rẹ̀ obinrin; ki o si jọwọ rẹ̀ lọ li omnira nitori ehín rẹ̀.