28 Bi akọmalu ba kàn ọkunrin tabi obinrin ti o si kú: sísọ ni ki a sọ akọmalu na li okuta pa bi o ti wù ki o ṣe, ki a má si ṣe jẹ ẹran rẹ̀; ṣugbọn ọrùn oni-akọmalu na yio mọ́.
29 Ṣugbọn bi o ba ṣepe akọmalu na a ti ma fi iwo rẹ̀ kàn nigba atijọ, ti a si ti kìlọ fun oluwa rẹ̀, ti kò si sé e mọ, ṣugbọn ti o pa ọkunrin tabi obinrin, akọmalu na li a o sọ li okuta pa, oluwa rẹ̀ li a o si lù pa pẹlu.
30 Bi o ba si ṣepe a bù iye owo kan fun u, njẹ iyekiye ti a bù fun u ni yio fi ṣe irapada ẹmi rẹ̀.
31 Iba kàn ọmọkunrin, tabi iba kàn ọmọbinrin, gẹgẹ bi irú idajọ yi li a o ṣe si i.
32 Bi akọmalu na ba kan ẹrukunrin tabi ẹrubirin; on o si san ọgbọ̀n ṣekeli fadakà fun oluwa rẹ̀, a o si sọ akọmalu na li okuta pa.
33 Bi ẹnikan ba ṣi ihò silẹ, tabi bi ọkunrin kan ba si wà ihò silẹ, ti kò si bò o, ti akọmalu tabi kẹtẹkẹtẹ ba bọ́ sinu rẹ̀;
34 Oni-ihò na yio si san; yio si fi owo fun oluwa wọn; okú ẹran a si jẹ́ tirẹ̀.