31 Iba kàn ọmọkunrin, tabi iba kàn ọmọbinrin, gẹgẹ bi irú idajọ yi li a o ṣe si i.
32 Bi akọmalu na ba kan ẹrukunrin tabi ẹrubirin; on o si san ọgbọ̀n ṣekeli fadakà fun oluwa rẹ̀, a o si sọ akọmalu na li okuta pa.
33 Bi ẹnikan ba ṣi ihò silẹ, tabi bi ọkunrin kan ba si wà ihò silẹ, ti kò si bò o, ti akọmalu tabi kẹtẹkẹtẹ ba bọ́ sinu rẹ̀;
34 Oni-ihò na yio si san; yio si fi owo fun oluwa wọn; okú ẹran a si jẹ́ tirẹ̀.
35 Bi akọmalu ẹnikan ba si pa akọmalu ẹnikeji lara ti o si kú; ki nwọn ki o tà ãye akọmalu, ki nwọn ki o si pín owo rẹ̀; oku ni ki nwọn ki o si pín pẹlu.
36 Tabi bi a ba si mọ̀ pe akọmalu na a ti ma kàn nigba atijọ ti oluwa rẹ̀ kò sé e mọ́; on o fi akọmalu san akọmalu nitõtọ; okú a si jẹ́ tirẹ̀.