5 Bi ẹru na ba si wi ni gbangba pe, Emi fẹ́ oluwa mi, aya mi, ati awọn ọmọ mi; emi ki yio jade lọ idi omnira:
6 Nigbana ni ki oluwa rẹ̀ ki o mú u lọ sọdọ awọn onidajọ; yio si mú u lọ si ẹnu-ọ̀na, tabi si opó ẹnu-ọ̀na; oluwa rẹ̀ yio si fi olù lú u li eti; on a si ma sìn i titi aiye.
7 Bi ẹnikan ba si tà ọmọ rẹ̀ obinrin li ẹrú, on ki yio jade lọ bi awọn ẹrú ọkunrin ti ijade lọ.
8 Bi on kò ba wù oluwa rẹ̀, ti o ti fẹ́ ẹ fun ara rẹ̀, njẹ ki o jẹ ki a rà a pada, on ki yio lagbara lati tà a fun ajeji enia, o sa ti tàn a jẹ.
9 Bi o ba si fẹ́ ẹ fun ọmọkunrin rẹ̀, ki o ma ṣe si i bi a ti iṣe si ọmọbinrin ẹni.
10 Bi o ba si fẹ́ obinrin miran; onjẹ rẹ̀, aṣọ rẹ̀, ati iṣe ọkọlaya rẹ̀, ki o máṣe yẹ̀.
11 Bi on ki yio ba si ṣe ohun mẹtẹta yi fun u, njẹ ki on ki o jade kuro lọfẹ li aisan owo.