7 Bi ẹnikan ba si tà ọmọ rẹ̀ obinrin li ẹrú, on ki yio jade lọ bi awọn ẹrú ọkunrin ti ijade lọ.
8 Bi on kò ba wù oluwa rẹ̀, ti o ti fẹ́ ẹ fun ara rẹ̀, njẹ ki o jẹ ki a rà a pada, on ki yio lagbara lati tà a fun ajeji enia, o sa ti tàn a jẹ.
9 Bi o ba si fẹ́ ẹ fun ọmọkunrin rẹ̀, ki o ma ṣe si i bi a ti iṣe si ọmọbinrin ẹni.
10 Bi o ba si fẹ́ obinrin miran; onjẹ rẹ̀, aṣọ rẹ̀, ati iṣe ọkọlaya rẹ̀, ki o máṣe yẹ̀.
11 Bi on ki yio ba si ṣe ohun mẹtẹta yi fun u, njẹ ki on ki o jade kuro lọfẹ li aisan owo.
12 Ẹniti o ba lù enia, tobẹ̃ ti o si ku, pipa li a o pa a.
13 Bi o ba ṣepe enia kò ba dèna, ṣugbọn ti o ṣepe Ọlọrun li o fi lé e lọwọ, njẹ emi o yàn ibi fun ọ, nibiti on o gbé salọ si.