5 Bi ọkunrin kan ba mu ki a jẹ oko tabi agbalá-àjara kan, ti o si tú ẹran rẹ̀ silẹ, ti o si jẹ li oko ẹlomiran; ninu ãyo oko ti ara rẹ̀, ati ninu ãyo agbalá-àjara tirẹ̀, ni yio fi san ẹsan.
6 Bi iná ba ṣẹ̀, ti o si mu ẹwọn, ti abà ọkà, tabi ọkà aiṣá, tabi oko li o joná; ẹniti o ràn iná na yio san ẹsan nitõtọ.
7 Bi ẹnikan ba fi owo tabi ohunèlo fun ẹnikeji rẹ̀ pamọ́; ti a ji i ni ile ọkunrin na; bi a ba mu olè na, ki o san a ni meji.
8 Bi a kò ba mú olè na, njẹ ki a mú bale na wá siwaju awọn onidajọ, bi on kò ba fọwọkàn ẹrù ẹnikeji rẹ̀.
9 Nitori irú ẹ̀ṣẹ gbogbo, iba ṣe ti akọmalu, ti kẹtẹkẹtẹ, ti agutan, ti aṣọ, tabi ti irũru ohun ti o nù, ti ẹlomiran pè ni ti on, ẹjọ́ awọn mejeji yio wá siwaju awọn onidajọ; ẹniti awọn onidajọ ba dẹbi fun, on o san a ni iṣẹmeji fun ẹnikeji rẹ̀.
10 Bi enia ba fi kẹtẹkẹtẹ, tabi akọmalu, tabi agutan, tabi ẹrankẹran lé ẹnikeji rẹ̀ lọwọ lati ma sìn; ti o ba si kú, tabi ti o farapa, tabi ti a lé e sọnù, ti ẹnikan kò ri i;
11 Ibura OLUWA yio wà lãrin awọn mejeji, pe, on kò fọwọkàn ẹrù ẹnikeji on; ki on ki o si gbà, on ki yio si san ẹsan.