9 Nitori irú ẹ̀ṣẹ gbogbo, iba ṣe ti akọmalu, ti kẹtẹkẹtẹ, ti agutan, ti aṣọ, tabi ti irũru ohun ti o nù, ti ẹlomiran pè ni ti on, ẹjọ́ awọn mejeji yio wá siwaju awọn onidajọ; ẹniti awọn onidajọ ba dẹbi fun, on o san a ni iṣẹmeji fun ẹnikeji rẹ̀.
10 Bi enia ba fi kẹtẹkẹtẹ, tabi akọmalu, tabi agutan, tabi ẹrankẹran lé ẹnikeji rẹ̀ lọwọ lati ma sìn; ti o ba si kú, tabi ti o farapa, tabi ti a lé e sọnù, ti ẹnikan kò ri i;
11 Ibura OLUWA yio wà lãrin awọn mejeji, pe, on kò fọwọkàn ẹrù ẹnikeji on; ki on ki o si gbà, on ki yio si san ẹsan.
12 Bi o ba ṣepe a ji i lọwọ rẹ̀, on o san ẹsan fun oluwa rẹ̀.
13 Bi o ba ṣepe a si fà a ya, njẹ ki o mú u wa ṣe ẹrí, on ki yio si san ẹsan eyiti a fàya.
14 Bi enia ba si yá ohun kan lọwọ ẹnikeji rẹ̀, ti o si farapa, tabi ti o kú, ti olohun kò si nibẹ̀, on o san ẹsan nitõtọ.
15 Ṣugbọn bi olohun ba wà nibẹ̀, on ki yio san ẹsan: bi o ba ṣe ohun ti a fi owo gbà lò ni, o dé fun owo igbàlo rẹ̀.