2 Iwọ kò gbọdọ tọ̀ ọ̀pọlọpọ enia lẹhin lati ṣe ibi, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ sọ̀rọ̀ li ọ̀ran ki o tẹ̀ si ọ̀pọ enia lati yi ẹjọ́ po.
3 Bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ gbè talaka li ẹjọ́ rẹ̀.
4 Bi iwọ ba bá akọmalu tabi kẹtẹkẹtẹ ọtá rẹ ti o ṣina, ki iwọ ki o mú u pada fun u wá nitõtọ.
5 Bi iwọ ba ri kẹtẹkẹtẹ ẹniti o korira rẹ, ti o dubulẹ labẹ ẹrù rẹ̀, ti iwọ iba yẹra lati bá a tú u, iwọ o bá a tú u nitõtọ.
6 Iwọ kò gbọdọ yi ẹjọ́ talaka rẹ po li ọ̀ran rẹ̀.
7 Takéte li ọ̀ran eke; ati alaiṣẹ ati olododo ni iwọ kò gbọdọ pa: nitoriti emi ki yio dá enia buburu lare.
8 Iwọ kò gbọdọ gbà ọrẹ: nitori ọrẹ ni ifọ́ awọn ti o riran loju, a si yi ọ̀ran awọn olododo po.