23 Nitoriti angeli mi yio ṣaju rẹ, yio si mú ọ dé ọdọ awọn enia Amori, ati awọn Hitti, ati awọn Perissi, ati awọn ara Kenaani, awọn Hifi, ati awọn Jebusi: emi a si ke wọn kuro.
24 Iwọ kò gbọdọ tẹriba fun oriṣa wọn, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ sìn wọn, ki o má si ṣe gẹgẹ bi iṣe wọn: bikoṣepe ki iwọ ki o fọ́ wọn tútu, ki iwọ ki o si wó ere wọn palẹ.
25 Ẹnyin o si ma sìn OLUWA Ọlọrun nyin, on o si busi onjẹ rẹ, ati omi rẹ; emi o si mú àrun kuro lãrin rẹ.
26 Obinrin kan ki yio ṣẹ́nu, bẹ̃ni ki yio yàgan ni ilẹ rẹ: iye ọjọ́ rẹ li emi ó fi kún.
27 Emi o rán ẹ̀ru mi siwaju rẹ, emi o si dà gbogbo awọn enia rú ọdọ ẹniti iwọ o dé, emi o si mu gbogbo awọn ọtá rẹ yi ẹ̀hin wọn dà si ọ.
28 Emi o si rán agbọ́n siwaju rẹ, ti yio lé awọn enia Hifi, ati awọn ara Kenaani, ati awọn enia Hitti kuro niwaju rẹ.
29 Emi ki yio lé wọn jade kuro niwaju rẹ li ọdún kan; ki ilẹ na ki o má ba di ijù, ki ẹranko igbẹ́ ki o má ba rẹ̀ si ọ.