7 O si mú iwé majẹmu nì, o si kà a li eti awọn enia: nwọn si wipe, Gbogbo eyiti OLUWA wi li awa o ṣe, awa o si gbọràn.
8 Mose si mú ẹ̀jẹ na, o si wọ́n ọ sara awọn enia, o si wipe, Kiyesi ẹ̀jẹ majẹmu, ti OLUWA bá nyin dá nipasẹ ọ̀rọ gbogbo wọnyi.
9 Nigbana ni Mose, ati Aaroni, Nadabu, ati Abihu, ati ãdọrin ninu awọn àgba Israeli gòke lọ:
10 Nwọn si ri Ọlọrun Israeli; bi iṣẹ okuta Safire wà li abẹ ẹsẹ̀ rẹ̀, o si dabi irisi ọrun ni imọ́toto rẹ̀.
11 Kò si nà ọwọ́ rẹ̀ lé awọn ọlọlá ọmọ Israeli: nwọn si ri Ọlọrun, nwọn si jẹ, nwọn si mu.
12 OLUWA si wi fun Mose pe, Gòke tọ̀ mi wá sori òke, ki o si duro nibẹ̀; emi o si fi walã okuta fun ọ, ati aṣẹ kan, ati ofin ti mo ti kọ, ki iwọ ki o le ma kọ́ wọn.
13 Mose si dide, ati Joṣua iranṣẹ rẹ̀: Mose si gòke lọ si oke Ọlọrun.