3 Aṣọ-tita marun ni ki a solù mọ́ ara wọn; ati aṣọ-tita marun keji ni ki a solù mọ́ ara wọn.
4 Iwọ o si ṣe ojóbo aṣọ-alaró si eti aṣọ-tita kan lati iṣẹti rẹ̀ wá ni ibi isolù, ati bẹ̃ gẹgẹ ni iwọ o ṣe li eti ikangun aṣọ-tita keji, ni ibi isolù keji.
5 Ãdọta ojóbo ni ki iwọ ki o ṣe si aṣọ-tita kan, ãdọta ojóbo ni ki iwọ ki o si ṣe si eti aṣọ-tita ti o wà ni isolù keji; ki ojóbo ki o le kọ́ ara wọn.
6 Iwọ o si ṣe ãdọta ikọ́ wurà, iwọ o si fi ikọ́ na fà awọn aṣọ-tita so: on o si jẹ́ agọ́ kan.
7 Iwọ o si ṣe aṣọ-tita irun ewurẹ, lati ṣe ibori sori agọ́ na: aṣọ-tita mọkanla ni iwọ o ṣe e.
8 Ìna aṣọ-tita kan yio jẹ́ ọgbọ̀n igbọnwọ, ati ibò aṣọ-tita kan yio jẹ́ igbọnwọ mẹrin: aṣọ-tita mọkọkanla na yio si jẹ́ ìwọn kanna.
9 Iwọ o si so aṣọ-tita marun lù mọ́ ara wọn li ọ̀tọ, ati aṣọ-tita mẹfa lù mọ́ ara wọn li ọ̀tọ, iwọ o si ṣẹ aṣọ-tita kẹfa po ni meji niwaju agọ́ na.