31 Iwọ o si ṣe aṣọ-ikele alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, ati ọ̀gbọ olokùn wiwẹ ti iṣẹ ọlọnà: ti on ti awọn kerubu nì ki a ṣe e:
32 Iwọ o si fi rọ̀ sara opó igi ṣittimu mẹrin, ti a fi wurà bò, wurà ni ikọ́ wọn lori ihò-ìtẹbọ fadakà mẹrẹrin na.
33 Iwọ o si ta aṣọ-ikele na si abẹ ikọ́ wọnni, ki iwọ ki o le mú apoti ẹrí nì wá si inu aṣọ-ikele nì: aṣọ-ikele nì ni yio si pinya lãrin ibi mimọ́ ati ibi mimọ́ julọ fun nyin.
34 Iwọ o si fi itẹ́-ãnu sori apoti ẹrí nì, ni ibi mimọ́ julọ.
35 Iwọ o si gbé tabili na kà ẹhin ode aṣọ-ikele nì, ati ọpá-fitila nì kọjusi tabili na ni ìha agọ́ na ni ìha gusù: iwọ o si gbé tabili na kà ìha ariwa.
36 Iwọ o si ṣe aṣọ-tita kan fun ẹnu-ọ̀na agọ́ na, ti aṣọ-alaró, ti elesè-aluko, ti ododó, ati ti ọ̀gbọ olokùn wiwẹ, ti a fi iṣẹ abẹ́rẹ ṣe.
37 Iwọ o si ṣe opó igi ṣittimu marun fun aṣọ-tita na, ki o si fi wurà bò wọn; ati ikọ́ wọn wurà: iwọ o si dà ihò-ìtẹbọ idẹ marun fun wọn.