1 IWỌ o si tẹ́ pẹpẹ igi ṣittimu kan, ìna rẹ̀ igbọnwọ marun, ati ìbú rẹ̀ igbọnwọ marun; ìwọn kan ni ìha mẹrẹrin: igbọnwọ mẹta si ni giga rẹ̀.
2 Iwọ o si ṣe iwo rẹ̀ si ori igun mẹrẹrin rẹ̀: iwo rẹ̀ yio si wà lara rẹ̀: iwọ o si fi idẹ bò o.
3 Iwọ o si ṣe tasà rẹ̀ lati ma gbà ẽru rẹ̀, ati ọkọ́ rẹ̀, ati awokòto rẹ̀ ati kọkọrọ ẹran rẹ̀, ati awo-iná rẹ̀ wọnni: gbogbo ohun-èlo rẹ̀ ni iwọ o fi idẹ ṣe.
4 Iwọ o si ṣe oju-àro idẹ fun u ni iṣẹ-àwọn; lara àwọn na ni ki iwọ ki o ṣe oruka mẹrin ni igun mẹrẹrin rẹ̀.
5 Iwọ o si fi si abẹ ayiká pẹpẹ na nisalẹ, ki àwọn na ki o le dé idaji pẹpẹ na.
6 Iwọ o si ṣe ọpá fun pẹpẹ na, ọpá igi ṣittimu, iwọ o si fi idẹ bò wọn.
7 A o si fi ọpá rẹ̀ bọ̀ oruka wọnni, ọpá wọnni yio si wà ni ìha mejeji pẹpẹ na, lati ma fi rù u.