27 Iwọ o si yà igẹ̀ ẹbọ fifì na simimọ́, ati itan ẹbọ agbesọsoke, ti a fì, ti a si gbesọsoke ninu àgbo ìyasimimọ́ na, ani ninu eyiti iṣe ti Aaroni, ati ninu eyiti iṣe ti awọn ọmọ rẹ̀:
28 Eyi ni yio si ma ṣe ti Aaroni ati ti awọn ọmọ rẹ̀ ni ìlana lailai lọwọ awọn ọmọ Israeli: nitori ẹbọ agbesọsoke ni: ẹbọ agbesọsoke ni yio si ṣe lati ọwọ́ awọn ọmọ Israeli, ninu ẹbọ alafia wọn, ani ẹbọ agbesọsoke wọn si OLUWA.
29 Ati aṣọ mimọ́ ti Aaroni ni yio ṣe ti awọn ọmọ rẹ̀ lẹhin rẹ̀, lati ma fi oróro yàn wọn ninu wọn, ati lati ma yà wọn simimọ́ ninu wọn.
30 Ẹnikan ninu awọn ọmọ rẹ̀ ti o ba jẹ́ alufa ni ipò rẹ̀ ni yio mú wọn wọ̀ ni ijọ́ meje, nigbati o ba wá sinu agọ́ ajọ, lati ṣe ìsin ni ibi mimọ́ nì.
31 Iwọ o si mú àgbo ìyasimimọ́ nì, iwọ o si bọ̀ ẹran rẹ̀ ni ibi mimọ́ kan.
32 Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ yio si jẹ ẹran àgbo na, ati àkara na ti o wà ninu agbọ̀n nì, li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ.
33 Nwọn o si jẹ nkan wọnni ti a fi ṣètutu na, lati yà wọn simimọ́, ati lati sọ wọn di mimọ́: ṣugbọn alejò ni kò gbọdọ jẹ ninu rẹ̀, nitoripe mimọ́ ni.