36 Iwọ o si ma pa akọmalu kọkan li ojojumọ́ ṣe ẹbọ ẹ̀ṣẹ fun ètutu: iwọ o si wẹ̀ pẹpẹ na mọ́, nigbati iwọ ba ṣètutu si i tán, iwọ o si ta oróro si i lati yà a simimọ́.
37 Ni ijọ́ meje ni iwọ o fi ṣètutu si pẹpẹ na, iwọ o si yà a simimọ́: on o si ṣe pẹpẹ mimọ́ julọ; ohunkohun ti o ba fọwọkàn pẹpẹ na, mimọ́ ni yio jẹ́.
38 Njẹ eyi ni iwọ o ma fi rubọ lori pẹpẹ na; ọdọ-agutan meji ọlọdún kan li ojojumọ́ lailai.
39 Ọdọ-agutan kan ni iwọ o fi rubọ li owurọ̀; ati ọdọ-agutan keji ni iwọ o fi rubọ li aṣalẹ:
40 Ati idamẹwa òṣuwọn iyẹfun ti a fi idamẹrin hini oróro ti a gún pòlu; ati idamẹrin òṣuwọn hini ọti-waini fun ẹbọ mimu, fun ọdọ-agutan ekini.
41 Ọdọ-agutan keji ni ki iwọ ki o pa rubọ li aṣalẹ, iwọ o si ṣe si i gẹgẹ bi ẹbọ jijẹ owurọ̀, ati gẹgẹ bi ẹbọ mimu rẹ̀, fun õrùn didùn, ẹbọ ti a fi iná ṣe ni si OLUWA.
42 Ẹbọ sisun titilai ni yio ṣe lati irandiran nyin li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ niwaju OLUWA: nibiti emi o ma bá nyin pade lati ma bá ọ sọ̀rọ nibẹ̀.