43 Nibẹ̀ li emi o ma pade awọn ọmọ Israeli; a o si fi ogo mi yà agọ́ na simimọ́.
44 Emi o si yà agọ́ ajọ na simimọ́, ati pẹpẹ nì: emi o si yà Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ simimọ́, lati ma ṣe iṣẹ alufa fun mi.
45 Emi o si ma gbé ãrin awọn ọmọ Israeli, emi o si ma ṣe Ọlọrun wọn.
46 Nwọn o si mọ̀ pe emi li OLUWA Ọlọrun wọn, ti o mú wọn lati ilẹ Egipti jade wá, ki emi ki o le ma gbé ãrin wọn: emi li OLUWA Ọlọrun wọn.