30 Iwọ o si ta òróró sí Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀, iwọ o si yà wọn si mimọ́, ki nwọn ki o le ma ṣe alufa fun mi.
31 Iwọ o si sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Eyi ni yio ma ṣe oróro mimọ́ itasori fun mi lati irandiran nyin.
32 A ko gbọdọ dà a si ara enia, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ ṣe irú rẹ̀, ni ìwọn pipò rẹ̀: mimọ́ ni, yio si ma ṣe mimọ́ fun nyin.
33 Ẹnikẹni ti o ba pò bi irú rẹ̀, tabi ẹnikẹni ti o ba fi sara alejò ninu rẹ̀, on li a o si ke kuro ninu awọn enia rẹ̀.
34 OLUWA si wi fun Mose pe, Mú olõrùn didùn sọdọ rẹ, stakte, ati onika, ati galbanumu; olõrùn didùn wọnyi, pẹlu turari daradara: òṣuwọn kan na li olukuluku;
35 Iwọ o si ṣe e ni turari, apòlu nipa ọgbọ́n-ọnà alapòlu, ti a fi iyọ̀ si, ti o dara ti o si mọ́.
36 Iwọ o si gún diẹ ninu rẹ̀ kunna, iwọ o si fi i siwaju ẹrí ninu rẹ̀ ninu agọ́ ajọ, nibiti emi o gbé ma bá ọ pade: yio ṣe mimọ́ julọ fun nyin.