1 OLUWA si sọ fun Mose pe,
2 Wò ó, emi ti pè Besaleli li orukọ, ọmọ Uri, ọmọ Huri, ti ẹ̀ya Judah:
3 Emi si fi ẹmi Ọlọrun kún u li ọgbọ́n, ati li oyé, ati ni ìmọ, ati li onirũru iṣẹ-ọnà.
4 Lati humọ̀ alarabara iṣẹ, lati ṣiṣẹ ni wurà, ati ni fadakà, ati ni idẹ,
5 Ati li okuta gbigbẹ lati tò wọn, ati ni igi fifin, lati ṣiṣẹ li onirũru iṣẹ-ọnà.
6 Ati emi, kiyesi i, mo fi Oholiabu, ọmọ Ahisamaki, ti ẹ̀ya Dani, pẹlu rẹ̀; ati ninu ọkàn awọn ti iṣe ọlọgbọ́n inu ni mo fi ọgbọ́n si, ki nwọn ki o le ma ṣe ohun gbogbo ti mo palaṣẹ fun ọ:
7 Agọ́ ajọ na, ati apoti ẹrí nì, ati itẹ́-ãnu ti o wà lori rẹ̀, ati gbogbo ohunèlo Agọ́ na.