1 OLUWA si wi fun Mose pe, Dide, gòke lati ihin lọ, iwọ ati awọn enia na ti iwọ mú gòke lati ilẹ Egipti wá, si ilẹ ti mo ti bura fun Abrahamu, fun Isaaki, ati fun Jakobu, wipe, Irú-ọmọ rẹ li emi o fi i fun:
2 Emi o si rán angeli kan si iwaju rẹ; emi o si lé awọn ara Kenaani, awọn ara Amori, ati awọn ara Hitti, ati awọn ara Perissi, ati awọn ara Hifi, ati awọn ara Jebusi jade:
3 Si ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin; emi ki yio sa gòke lọ lãrin rẹ; nitori ọlọrùn lile ni iwọ: ki emi ki o má ba run ọ li ọ̀na.
4 Nigbati awọn enia na si gbọ́ ihin buburu yi, nwọn kãnu: enia kan kò si wọ̀ ohun ọṣọ́ rẹ̀.
5 OLUWA si ti wi fun Mose pe, Wi fun awọn ọmọ Israeli pe, ọlọ́rùn lile ni nyin: bi emi ba gòke wá sãrin rẹ ni iṣẹju kan, emi o si run ọ: njẹ nisisiyi bọ́ ohun ọṣọ́ rẹ kuro lara rẹ, ki emi ki o le mọ̀ ohun ti emi o fi ọ ṣe.