8 O si ṣe, nigbati Mose jade lọ si ibi agọ́ na, gbogbo awọn enia a si dide duro, olukuluku a si duro li ẹnu-ọ̀na agọ́ rẹ̀, a ma wò ẹhin Mose, titi yio fi dé ibi agọ́ na.
9 O si ṣe, bi Mose ti dé ibi agọ́ na, ọwọ̀n awọsanma sọkalẹ, o si duro li ẹnu-ọ̀na agọ́ na: OLUWA si bá Mose sọ̀rọ.
10 Gbogbo enia si ri ọwọ̀n awọsanma na o duro li ẹnu-ọ̀na agọ́ na: gbogbo enia si dide duro, nwọn si wolẹ sìn, olukuluku li ẹnu-ọ̀na agọ́ rẹ̀.
11 OLUWA si bá Mose sọ̀rọ li ojukoju, bi enia ti ibá ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ. O si tun pada lọ si ibudó: ṣugbọn Joṣua iranṣẹ rẹ̀, ọmọ Nuni, ọdọmọkunrin kan, kò lọ kuro ninu agọ́ na.
12 Mose si wi fun OLUWA pe, Wò o, iwọ wi fun mi pe, Mú awọn enia wọnyi gòke lọ: sibẹ̀ iwọ kò jẹ ki emi ki o mọ̀ ẹniti iwọ o rán pẹlu mi. Ṣugbọn iwọ wipe, Emi mọ̀ ọ li orukọ, iwọ si ri ore-ọfẹ li oju mi pẹlu.
13 Njẹ nisisiyi, emi bẹ̀ ọ, bi mo ba ri ore-ọfẹ li oju rẹ, fi ọ̀na rẹ hàn mi nisisiyi, ki emi ki o le mọ̀ ọ, ki emi ki o le ri ore-ọfẹ li oju rẹ: ki o si rò pe orilẹ-ède yi enia rẹ ni.
14 On si wipe, Oju mi yio ma bá ọ lọ, emi o si fun ọ ni isimi.