1 OLUWA si wi fun Mose pe, Iwọ gbẹ́ walã okuta meji bi ti iṣaju: emi o si kọ ọ̀rọ walã ti iṣaju, ti iwọ ti fọ́, sara walã wọnyi.
2 Si mura li owurọ̀, ki iwọ ki o si gún òke Sinai wá li owurọ̀, ki o si wá duro niwaju mi nibẹ̀ lori òke na.
3 Ẹnikẹni ki yio si bá ọ gòke wá, ki a má si ṣe ri ẹnikẹni pẹlu li òke na gbogbo; bẹ̃ni ki a máṣe jẹ ki agbo-agutan tabi ọwọ́-ẹran ki o jẹ niwaju òke na.
4 On si gbẹ́ walã okuta meji bi ti iṣaju; Mose si dide ni kutukutu owurọ̀, o si gún òke Sinai, bi OLUWA ti paṣẹ fun u, o si mú walã okuta mejeji li ọwọ́ rẹ̀.
5 OLUWA si sọkalẹ ninu awọsanma, o si bá a duro nibẹ̀, o si pè orukọ OLUWA.
6 OLUWA si rekọja niwaju rẹ̀, o si nkepè, OLUWA, OLUWA, Olọrun alãnu ati olore-ọfẹ, onipamọra, ati ẹniti o pọ̀ li ore ati otitọ;