28 Ati ninu ojidilẹgbẹsan ṣekeli o le mẹdogun, o mú ṣe kọkọrọ fun ọwọ̀n wọnni, o si fi i bò ori wọn, o si fi i ṣe ọjá wọn.
29 Ati idẹ ọrẹ na jẹ́ ãdọrin talenti, ati egbejila ṣekeli.
30 On li o si fi ṣe ihò-ìtẹbọ ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ ati pẹpẹ idẹ na, ati àro idẹ sara rẹ̀, ati gbogbo ohun-èlo pẹpẹ na,
31 Ati ihò-ìtẹbọ agbalá, na yikà, ati ìho-ìtẹbọ ẹnu-ọ̀na agbalá, ati gbogbo ekàn agọ́ na, ati gbogbo ekàn agbalà na yikà.