5 O si dà oruka mẹrin fun ìku mẹrẹrin àro idẹ na, li àye fun ọpá wọnni.
6 O si fi igi ṣittimu ṣe ọpá wọnni, o si fi idẹ bò wọn.
7 O si fi ọpá wọnni sinu oruka ni ìha pẹpẹ na, lati ma fi rù u; o fi apáko ṣe pẹpẹ na li onihò ninu.
8 O si fi idẹ ṣe agbada na, o si fi idẹ ṣe ẹsẹ̀ rẹ̀, ti awojiji ẹgbẹ awọn obinrin ti npejọ lati sìn li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ.
9 O si ṣe agbalá na: ni ìha gusù li ọwọ́ ọtún aṣọ-tita agbalá na jẹ́ ọ̀gbọ olokùn wiwẹ, ọgọrun igbọnwọ:
10 Opó wọn jẹ́ ogún, ihò-ìtẹbọ idẹ wọn jẹ́ ogún; kọkọrọ opó wọnni ati ọjá wọn jẹ́ fadakà.
11 Ati fun ìha ariwa ọgọrun igbọnwọ, opó wọn jẹ́ ogún, ati ihò-ìtẹbọ idẹ wọn jẹ́ ogún; kọkọrọ opó wọnni ati ọjá wọn jẹ́ fadakà.