10 Mose si wi fun OLUWA pe, Oluwa, emi ki iṣe ẹni ọ̀rọ-sisọ nigba atijọ wá, tabi lati igbati o ti mbá iranṣẹ rẹ sọ̀rọ: ṣugbọn olohùn wuwo ni mi, ati alahọn wuwo.
11 OLUWA si wi fun u pe, Tali o dá ẹnu enia? tabi tali o dá odi, tabi aditi, tabi ariran, tabi afọju? Emi OLUWA ha kọ́?
12 Njẹ lọ nisisiyi, emi o si pẹlu ẹnu rẹ, emi o si kọ́ ọ li eyiti iwọ o wi.
13 On si wipe, Oluwa, emi bẹ̀ ọ, rán ẹniti iwọ o rán.
14 Inu OLUWA si ru si Mose, o si wipe, Aaroni arakunrin rẹ ọmọ Lefi kò ha wà? Emi mọ̀ pe o le sọ̀rọ jọjọ. Ati pẹlu, kiyesi i, o si mbọ̀wá ipade rẹ: nigbati o ba si ri ọ, on o yọ̀ ninu ọkàn rẹ̀.
15 Iwọ o si sọ̀rọ fun u, iwọ o si fi ọ̀rọ si i li ẹnu: emi o si pẹlu ẹnu rẹ, ati pẹlu ẹnu rẹ̀, emi o si kọ́ nyin li eyiti ẹnyin o ṣe.
16 On ni yio si ma ṣe ogbifọ rẹ fun awọn enia: yio si ṣe, on o ma jẹ́ ẹnu fun ọ, iwọ o si ma jẹ́ bi Olọrun fun u.