15 Iwọ o si sọ̀rọ fun u, iwọ o si fi ọ̀rọ si i li ẹnu: emi o si pẹlu ẹnu rẹ, ati pẹlu ẹnu rẹ̀, emi o si kọ́ nyin li eyiti ẹnyin o ṣe.
16 On ni yio si ma ṣe ogbifọ rẹ fun awọn enia: yio si ṣe, on o ma jẹ́ ẹnu fun ọ, iwọ o si ma jẹ́ bi Olọrun fun u.
17 Iwọ o si mú ọpá yi li ọwọ́ rẹ, eyiti iwọ o ma fi ṣe iṣẹ-àmi.
18 Mose si lọ, o si pada tọ̀ Jetro ana rẹ̀, o si wi fun u pe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki nlọ ki emi si pada tọ̀ awọn arakunrin mi ti o wà ni Egipti, ki emi ki o si wò bi nwọn wà li ãye sibẹ̀. Jetro si wi fun Mose pe, Mã lọ li alafia.
19 OLUWA si wi fun Mose ni Midiani pe, Lọ, pada si Egipti: nitori gbogbo enia ti nwá ẹmi rẹ ti kú tán.
20 Mose si mú aya rẹ̀ ati awọn ọmọ-ọkunrin rẹ̀, o si gbé wọn gùn kẹtẹkẹtẹ kan, o si pada si ilẹ Egipti: Mose si mú ọpá Ọlọrun na li ọwọ́ rẹ̀.
21 OLUWA si wi fun Mose pe, Nigbati iwọ ba dé Egipti, kiyesi i ki iwọ ki o ṣe gbogbo iṣẹ-iyanu, ti mo filé ọ lọwọ, niwaju Farao, ṣugbọn emi o mu àiya rẹ̀ le, ti ki yio fi jẹ ki awọn enia na ki o lọ.