24 O si ṣe li ọ̀na ninu ile-èro, li OLUWA pade rẹ̀, o si nwá ọ̀na lati pa a.
25 Nigbana ni Sippora mú okuta mimú, o si kọ ọmọ rẹ̀ ni ilà abẹ, o si sọ ọ si ẹsẹ̀ Mose, o si wipe, Ọkọ ẹlẹjẹ ni iwọ fun mi nitõtọ.
26 Bẹ̃li o jọwọ rẹ̀ lọwọ lọ. Nigbana ni Sippora wipe, Ọkọ ẹlẹjẹ ni iwọ nitori ikọlà na.
27 OLUWA si wi fun Aaroni pe, Lọ si ijù lọ ipade Mose. On si lọ, o si pade rẹ̀ li oke Ọlọrun, o si fi ẹnu kò o li ẹnu.
28 Mose si sọ gbogbo ọ̀rọ OLUWA ti o rán a fun Aaroni, ati gbogbo aṣẹ iṣẹ-àmi ti o fi fun u.
29 Mose ati Aaroni si lọ, nwọn si kó gbogbo àgba awọn ọmọ Israeli jọ:
30 Aaroni si sọ gbogbo ọ̀rọ ti OLUWA ti sọ fun Mose, o si ṣe iṣẹ-àmi na li oju awọn enia na.