14 OLUWA si wi fun Mose pe, Aiya Farao di lile, o kọ̀ lati jẹ ki awọn enia na ki o lọ.
15 Tọ̀ Farao lọ li owurọ̀; kiyesi i, o njade lọ si odò; ki iwọ ki o si duro lati pade rẹ̀ leti odò; ati ọpá nì ti o di ejò ni ki iwọ ki o mú li ọwọ́ rẹ.
16 Iwọ o si wi fun u pe, OLUWA, Ọlọrun awọn Heberu, li o rán mi si ọ wipe, Jẹ ki awọn enia mi ki o lọ, ki nwọn ki o le sìn mi ni ijù: si kiyesi i, titi di isisiyi iwọ kò gbọ́.
17 Bayi li OLUWA wi, Ninu eyi ni iwọ o fi mọ̀ pe emi li OLUWA: kiyesi i, emi o fi ọpá ti o wà li ọwọ́ mi lù omi ti o wà li odò, nwọn o si di ẹ̀jẹ.
18 Ẹja ti o wà ninu odò na yio si kú, odò na yio si ma rùn; awọn ara Egipti yio si korira ati ma mu ninu omi odò na.
19 OLUWA si sọ fun Mose pe, Wi fun Aaroni pe, Mú ọpá rẹ, ki o si nà ọwọ́ rẹ si oju omi Egipti wọnni, si odò wọn, si omi ṣiṣàn wọn, ati ikudu wọn, ati si gbogbo ikojọpọ omi wọn, ki nwọn le di ẹ̀jẹ; ẹ̀jẹ yio si wà ni gbogbo ilẹ Egipti, ati ninu ohun-èlo igi, ati ninu ohun-èlo okuta.
20 Mose ati Aaroni si ṣe bẹ̃ bi OLUWA ti fi aṣẹ fun wọn; o si gbé ọpá na soke o si lù omi ti o wà li odò li oju Farao, ati li oju awọn iranṣẹ rẹ̀; a si sọ gbogbo omi ti o wà li odò na di ẹ̀jẹ.