18 Yio si jo ogo igbó rẹ̀ run, ati oko rẹ̀ ẹlẹtù loju, ati ọkàn ati ara: nwọn o si dabi igbati ọlọpagun ndakú.
19 Iyokù igi igbó rẹ̀ yio si jẹ diẹ, ti ọmọde yio le kọwe wọn.
20 Yio si ṣe li ọjọ na, iyokù Israeli, ati iru awọn ti o salà ni ile Jakobu, ki yio tun duro tì ẹniti o lù wọn mọ; ṣugbọn nwọn o duro tì Oluwa, Ẹni-Mimọ Israeli, li otitọ.
21 Awọn iyokù yio pada, awọn iyokù ti Jakobu, si Ọlọrun alagbara.
22 Bi Israeli enia rẹ ba dàbi iyanrìn okun, sibẹ iyokù ninu wọn o pada: aṣẹ iparun na yio kun àkúnwọ́sílẹ̀ ninu ododo.
23 Nitori Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun yio ṣe iparun, ani ipinnu, li ãrin ilẹ gbogbo.
24 Nitorina bayi li Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, Ẹnyin enia mi ti ngbe Sioni, ẹ má bẹ̀ru awọn ara Assiria: on o fi ọgọ lù ọ, yio si gbe ọpa rẹ̀ soke si ọ, gẹgẹ bi iru ti Egipti.