5 Ododo yio si jẹ amure ẹgbẹ́ rẹ̀, ati iṣotitọ amure inu rẹ̀.
6 Ikõkò pẹlu yio ma ba ọdọ-agutan gbe pọ̀, kiniun yio si dubulẹ pẹlu ọmọ ewurẹ; ati ọmọ malũ ati ọmọ kiniun ati ẹgbọ̀rọ ẹran abọpa yio ma gbe pọ̀; ọmọ kekere yio si ma dà wọn.
7 Malũ ati beari yio si ma jẹ pọ̀; ọmọ wọn yio dubulẹ pọ̀; kiniun yio si jẹ koriko bi malũ.
8 Ọmọ ẹnu-ọmu yio si ṣire ni ihò pãmọlẹ, ati ọmọ ti a já lẹnu-ọmu yio si fi ọwọ́ rẹ̀ si ihò ejò.
9 Nwọn ki yio panilara, bẹ̃ni nwọn ki yio panirun ni gbogbo oke mimọ́ mi: nitori aiye yio kún fun ìmọ Oluwa gẹgẹ bi omi ti bò okun.
10 Ati li ọjọ na kùkute Jesse kan yio wà, ti yio duro fun ọpágun awọn enia; on li awọn keferi yio wá ri: isimi rẹ̀ yio si li ogo.
11 Yio si ṣe li ọjọ na, ni Oluwa yio tun nawọ rẹ̀ lati gbà awọn enia rẹ̀ iyokù padà, ti yio kù, lati Assiria, ati lati Egipti, ati lati Patrosi, ati lati Kuṣi, ati lati Elamu, ati Ṣinari, ati lati Hamati, ati lati awọn erekùṣu okun wá.