3 Ẹnyin o si fi ayọ̀ fà omi jade lati inu kanga igbala wá.
4 Li ọjọ na li ẹnyin o si wipe, Yìn Oluwa, kepe orukọ rẹ̀, sọ iṣẹ́ rẹ̀ lãrin awọn enia, mu u wá si iranti pe, orukọ rẹ̀ li a gbe leke.
5 Kọrin si Oluwa: nitori o ti ṣe ohun didara: eyi di mimọ̀ ni gbogbo aiye.
6 Kigbe, si hó, iwọ olugbe Sioni: nitori ẹni titobi ni Ẹni-Mimọ́ Israeli li ãrin rẹ.