6 Ẹ hu; nitori ọjọ Oluwa kù si dẹdẹ; yio de bi iparun lati ọdọ Olodumare wá.
7 Nitorina gbogbo ọwọ́ yio rọ, ọkàn olukuluku enia yio si di yiyọ́.
8 Nwọn o si bẹ̀ru: irora ati ikãnu yio dì wọn mu; nwọn o wà ni irora bi obinrin ti nrọbi: ẹnu yio yà ẹnikan si ẹnikeji rẹ̀; oju wọn yio dabi ọwọ́-iná.
9 Kiyesi i, ọjọ Oluwa mbọ̀ wá, o ni ibi ti on ti ikannú ati ibinu gbigboná, lati sọ ilẹ na di ahoro: yio si pa awọn ẹlẹṣẹ run kuro ninu rẹ̀.
10 Nitori awọn iràwọ ọrun, ati iṣùpọ iràwọ inu rẹ̀ kì yio tàn imọlẹ wọn: õrun yio ṣu okùnkun ni ijadelọ rẹ̀, oṣùpa kì yio si mu ki imọlẹ rẹ̀ tàn.
11 Emi o si bẹ̀ ibi wò lara aiye, ati aiṣedẽde lara awọn enia buburu; emi o si mu ki igberaga awọn agberaga ki o mọ, emi o si mu igberaga awọn alagbara rẹ̀ silẹ.
12 Emi o mu ki ọkunrin kan ṣọwọ́n ju wura lọ; ani enia kan ju wura Ofiri daradara.