8 Nitõtọ, igi firi nyọ̀ ọ, ati igi kedari ti Lebanoni, wipe, Lati ìgba ti iwọ ti dubulẹ, kò si akegi ti o tọ̀ wa wá.
9 Ipò-okú lati isalẹ wá mì fun ọ lati pade rẹ li àbọ rẹ: o rú awọn okú dide fun ọ, ani gbogbo awọn alakoso aiye; o ti gbe gbogbo ọba awọn orilẹ-ède dide kuro lori itẹ wọn.
10 Gbogbo wọn o dahùn, nwọn o si wi fun ọ pe, Iwọ pẹlu ti di ailera gẹgẹ bi awa? iwọ ha dabi awa?
11 Ogo rẹ li ati sọ̀kalẹ si ipò-okú, ati ariwo durù rẹ: ekòlo ti tàn sabẹ rẹ, idin si bò ọ mọ ilẹ.
12 Bawo ni iwọ ti ṣe ṣubu lati ọrun wá, Iwọ Lusiferi, iràwọ owurọ! bawo li a ti ṣe ke ọ lu ilẹ, iwọ ti o ti ṣẹ́ awọn orilẹ-ède li apa!
13 Nitori iwọ ti wi li ọkàn rẹ pe, Emi o goke lọ si ọrun, emi o gbe itẹ mi ga kọja iràwọ Ọlọrun: emi o si joko lori oke ijọ enia ni iha ariwa:
14 Emi o goke kọja giga awọsanma: emi o dabi ọga-ogo jùlọ.