3 Ẹ gbìmọ, ẹ mu idajọ ṣẹ; ṣe ojiji rẹ bi oru li ãrin ọsángangan; pa awọn ti a le jade mọ́; máṣe fi isánsa hàn.
4 Moabu, jẹ ki awọn isánsa mi ba ọ gbe, iwọ ma jẹ ãbo fun wọn li oju akoni: nitori alọnilọwọgbà de opin, akoni dasẹ̀, a pa awọn aninilara run kuro lori ilẹ.
5 Ninu ãnu li a o si fi idi ilẹ mulẹ: yio si joko lori rẹ̀ li otitọ ninu agọ Dafidi, yio ma ṣe idajọ, yio si ma wá idajọ, yio si ma mu ododo yara kánkán.
6 Awa ti gbọ́ ti igberaga Moabu; o gberaga pọju: ani ti irera rẹ̀, ati igberaga rẹ̀, ati ibinu rẹ̀; ihalẹ rẹ̀ asan ni.
7 Nitorina ni Moabu yio hu fun Moabu, gbogbo wọn o hu: nitori ipilẹ Kir-haresi li ẹnyin o gbàwẹ; nitõtọ a lù wọn.
8 Nitori igbẹ́ Heṣboni rọ, ati àjara Sibma: awọn oluwa awọn keferi ti ke pataki ọ̀gbin rẹ̀ lu ilẹ, nwọn tàn de Jaseri, nwọn nrìn kakiri aginjù: ẹka rẹ̀ nà jade, nwọn kọja okun.
9 Nitorina emi o pohùnrére ẹkun, bi ẹkun Jaseri, àjara Sibma: emi o fi omije mi rin ọ, iwọ Heṣboni, ati Eleale: nitori ariwo nla ta lori èso-igi ẹ̃rùn rẹ, ati lori ikore rẹ.