6 Odò yio si di rirùn; odò ãbo li a o sọ di ofo, ti a o si gbọ́n gbẹ; oko-odò ati iyè yio rọ.
7 Oko-tutù ni ipadò, li ẹnu odò, ati ohun gbogbo ti a gbìn sipadò, ni yio rọ, yio funka, kì yio si si mọ.
8 Awọn apẹja yio gbàwẹ pẹlu, ati gbogbo awọn ti nfì ìwọ li odò yio pohùnrére-ẹkun; ati awọn ti nda àwọn li odò yio sorikọ́.
9 Pẹlupẹlu awọn ti nṣiṣẹ ọ̀gbọ daradara, ati awọn ti nwun asọ-àla yio dãmu.
10 A o si fọ́ wọn ni ipilẹ rẹ̀, gbogbo awọn alagbàṣe li a o bà ni inu jẹ.
11 Nitõtọ òpe ni awọn ọmọ-alade Soani, ìmọ awọn ìgbimọ ọlọgbọn Farao di wère: ẹ ha ti ṣe sọ fun Farao, pe, Emi li ọmọ ọlọgbọn, ọmọ awọn ọba igbãni?
12 Awọn dà? awọn ọlọgbọn rẹ dà? si jẹ ki wọn sọ fun ọ nisisiyi, si jẹ ki wọn mọ̀ ete ti Oluwa awọn ọmọ-ogun ti pa le Egipti.