18 Yio si ṣe, ẹniti o sá kuro fun ariwo ìbẹru yio jin sinu ọ̀fin; ati ẹniti o jade lati inu ọ̀fin wá li a o fi ẹgẹ́ mu: nitori awọn ferese lati oke wá ṣi silẹ, ipilẹ ilẹ si mì.
19 Ilẹ di fifọ́ patapata, ilẹ di yíyọ patapata, ilẹ mì tìtì.
20 Ilẹ yio ta gbọ̀ngbọn sihin sọhun bi ọ̀mutí, a o si ṣi i ni idí bi agọ́; irekọja inu rẹ̀ yio wọ̀ ọ li ọrùn; yio si ṣubu, kì yio si dide mọ́.
21 Yio si ṣe li ọjọ na, Oluwa yio bẹ̀ ogun awọn ẹni-giga ni ibi-giga wò, ati awọn ọba aiye li aiye.
22 A o si ko wọn jọ pọ̀, bi a iti kó ara tubu jọ sinu ihò, a o tì wọn sinu tubu, lẹhin ọjọ pupọ̀ li a o si bẹ̀ wọn wò.
23 Nigbana li a o dãmu oṣupa, oju yio si tì õrun, nigbati Oluwa awọn ọmọ-ogun yio jọba li oke Sioni, ati ni Jerusalemu, ogo yio si wà niwaju awọn alàgba rẹ̀.