2 Yio si ṣe, bi o ti ri fun awọn enia, bẹ̃li o ri fun alufa; bi o ti ri fun iranṣẹ-kunrin, bẹ̃ni fun oluwa rẹ̀; bi o ti ri fun iranṣẹbinrin, bẹ̃ni fun oluwa rẹ̀; bi o ti ri fun olùra, bẹ̃ni fun olùta; bi o ti ri fun awinni, bẹ̃ni fun atọrọ; bi o ti ri fun agbà elé, bẹ̃ni fun ẹniti o san ele fun u.
3 Ilẹ yio di ofo patapata, yio si bajẹ patapata: nitori Oluwa ti sọ ọ̀rọ yi.
4 Ilẹ̀ nṣọ̀fọ o si nṣá, aiye nrù o si nṣá, awọn ẹni giga ilẹ njoro.
5 Ilẹ pẹlu si di aimọ́ li abẹ awọn ti ngbe inu rẹ̀; nitori nwọn ti rú ofin, nwọn pa ilàna dà, nwọn dà majẹmu aiyeraiye.
6 Nitorina ni egún ṣe jẹ ilẹ run, awọn ti ngbe inu rẹ̀ di ahoro: nitorina ni awọn ti ngbe ilẹ jona, enia diẹ li o si kù.
7 Ọti-waini titun nṣọ̀fọ, àjara njoro, gbogbo awọn ti nṣe aríya nkẹdùn.
8 Ayọ̀ tabreti dá, ariwo awọn ti nyọ̀ pin, ayọ̀ harpu dá.