1 OLUWA, iwọ li Ọlọrun mi; emi o gbe ọ ga, emi o yìn orukọ rẹ; nitori iwọ ti ṣe ohun iyanu; ìmọ igbani, ododo ati otitọ ni.
2 Nitori iwọ ti sọ ilu kan di okiti; iwọ ti sọ ilu olodi di iparun: ãfin awọn alejo, kò jẹ ilu mọ́; a kì yio kọ́ ọ mọ.
3 Nitorina ni awọn alagbara enia yio yìn ọ li ogo, ilu orilẹ-ède ti o ni ibẹ̀ru yio bẹ̀ru rẹ.
4 Nitori iwọ ti jẹ agbara fun talaka, agbara fun alaini ninu iṣẹ́ rẹ̀, ãbo kuro ninu ìji, ojiji kuro ninu oru, nigbati ẹfũfu lile awọn ti o ni ibẹ̀ru dabi ìji lara ogiri.
5 Iwọ o mu ariwo awọn alejo rọlẹ, gẹgẹ bi oru nibi gbigbẹ; ani oru pẹlu ojiji awọsanma: a o si rẹ̀ orin-ayọ̀ awọn ti o ni ibẹ̀ru silẹ.