3 Nitorina ni awọn alagbara enia yio yìn ọ li ogo, ilu orilẹ-ède ti o ni ibẹ̀ru yio bẹ̀ru rẹ.
4 Nitori iwọ ti jẹ agbara fun talaka, agbara fun alaini ninu iṣẹ́ rẹ̀, ãbo kuro ninu ìji, ojiji kuro ninu oru, nigbati ẹfũfu lile awọn ti o ni ibẹ̀ru dabi ìji lara ogiri.
5 Iwọ o mu ariwo awọn alejo rọlẹ, gẹgẹ bi oru nibi gbigbẹ; ani oru pẹlu ojiji awọsanma: a o si rẹ̀ orin-ayọ̀ awọn ti o ni ibẹ̀ru silẹ.
6 Ati ni oke-nla yi li Oluwa awọn ọmọ-ogun yio sè asè ohun abọ́pa fun gbogbo orilẹ-ède, asè ọti-waini lori gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ, ti ohun abọpa ti o kún fun ọra, ti ọti-waini ti o tòro lori gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ.
7 Li oke-nla yi on o si pa iboju ti o bò gbogbo enia loju run, ati iboju ti a nà bò gbogbo orilẹ-ède.
8 On o gbe iku mì lailai; Oluwa Jehofah yio nù omije nù kuro li oju gbogbo enia; yio si mu ẹ̀gan enia rẹ̀ kuro ni gbogbo aiye: nitori Oluwa ti wi i.
9 A o si sọ li ọjọ na pe, Wò o, Ọlọrun wa li eyi; awa ti duro de e, on o si gbà wa là: Oluwa li eyi: awa ti duro de e, awa o ma yọ̀, inu wa o si ma dùn ninu igbala rẹ̀.