8 Niwọ̀n-niwọ̀n, nigba itìjade rẹ̀, iwọ o ba a wi: on ṣi ẹfũfu-ile rẹ̀ ni ipò li ọjọ ẹfũfu ilà-õrun.
9 Nitorina nipa eyi li a o bò ẹ̀ṣẹ Jakobu mọlẹ: eyi si ni gbogbo eso lati mu ẹ̀ṣẹ rẹ̀ kuro; nigbati on gbe okuta pẹpẹ kalẹ bi okuta ẹfun ti a lù wẹwẹ, igbó ati ere-õrun kì yio dide duro.
10 Nitori ilu-olodi yio di ahoro, a o si kọ̀ ibugbé silẹ, a o si fi i silẹ bi aginju: nibẹ ni ọmọ-malu yio ma jẹ̀, nibẹ ni yio si dubulẹ, yio si jẹ ẹka rẹ̀ run.
11 Nigbati ẹka inu rẹ̀ ba rọ, a o ya wọn kuro: awọn obinrin de, nwọn si tẹ̀ iná bọ̀ wọn: nitori alaini oye enia ni nwọn: nitorina ẹniti o dá wọn kì yio ṣãnu fun wọn, ẹniti o si mọ wọn kì yio fi ojurere hàn wọn.
12 Yio si ṣe li ọjọ na, Oluwa yio ja eso kuro ni ibu odò si iṣàn Egipti, a o si ṣà nyin jọ li ọkọkan, ẹnyin ọmọ Israeli.
13 Yio si ṣe li ọjọ na, a o fun ipè nla, awọn ti o mura lati ṣegbe ni ilẹ Assiria yio si wá, ati awọn aṣátì ilẹ Egipti, nwọn o si sìn Oluwa ni oke mimọ́ ni Jerusalemu.