12 Si ẹniti on wipe, Eyi ni isimi, ẹnyin ìba mu awọn alãrẹ̀ simi; eyi si ni itura: sibẹ nwọn kì yio gbọ́.
13 Nitorina ọ̀rọ Oluwa jẹ aṣẹ le aṣẹ, aṣẹ le aṣẹ fun wọn: ẹsẹ le ẹsẹ, ẹsẹ le ẹsẹ; diẹ nihin, diẹ lọhun: ki nwọn ba le lọ, ki nwọn si ṣubu sẹhin, ki nwọn si ṣẹ́, ki a si dẹ wọn, ki a si mu wọn.
14 Nitorina ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin ẹlẹgàn, ti nṣe akoso awọn enia yi ti mbẹ ni Jerusalemu.
15 Nitori ẹnyin ti wipe, Awa ti ba ikú dá majẹmu, a si ti ba ipò-okú mulẹ: nigbati pàṣan gigun yio là a já, kì yio de ọdọ wa: nitori awa ti fi eké ṣe ãbo wa, ati labẹ irọ́ li awa ti fi ara wa pamọ:
16 Nitorina bayi li Oluwa Jehofah wi, pe, Kiyesi i, emi gbe okuta kan kalẹ ni Sioni fun ipilẹ, okuta ti a dán wò, okuta igun-ile iyebiye, ipilẹ ti o daju: ẹniti o gbagbọ kì yio sá.
17 Idajọ li emi o fi le ẹsẹ pẹlu, ati ododo li emi o fi lé òṣuwọn: yinyín yio gbá ãbo eke lọ, omi o si kún bò ibi isasi mọlẹ.
18 Majẹmu nyin ti ẹ ba ikú dá li a o sọ di asan, imulẹ nyin pẹlu ipò-okú kì yio duro; nigbati paṣán gigun yio rekọja; nigbana ni on o tẹ̀ nyin mọlẹ.