17 Oju rẹ̀ yio ri ọba ninu ẹwà rẹ̀: nwọn o ma wò ilẹ ti o jina réré.
18 Aiyà rẹ yio ṣe aṣaro ẹ̀ru nla. Nibo ni akọwe wà? nibo ni ẹniti nwọ̀n nkan gbe wà? nibo ni ẹniti o nkà ile-ẹ̀ṣọ wọnni gbe wà?
19 Iwọ kì yio ri awọn enia ti o muná; awọn enia ti ọ̀rọ wọn jinlẹ jù eyiti iwọ le gbọ́, ti ahọn wọn ṣe ololò, ti kò le ye ọ.
20 Wo Sioni, ilu ajọ afiyesi wa: oju rẹ yio ri Jerusalemu ibugbe idakẹjẹ, agọ́ ti a kì yio tú palẹ mọ; kò si ọkan ninu ẽkàn rẹ ti a o ṣí ni ipò lai, bẹ̃ni kì yio si ọkan ninu okùn rẹ̀ ti yio já.
21 Ṣugbọn nibẹ ni Oluwa ogo yio ri fun wa, bi ibi odò gbigbòro on odò ṣiṣàn; nibiti ọkọ̀ alajẹ̀ kì yio kọja, bẹ̃ni ọkọ̀ nlanla ki yio là a ja.
22 Nitori Oluwa ni onidajọ wa, Oluwa li olofin wa, Oluwa li ọba wa; on o gbà wa là.
23 Okùn opó-ọkọ̀ rẹ tú; nwọn kò le dì opó-ọkọ̀ mu le danin-danin, nwọn kò le ta igbokun: nigbana li a pin ikogun nla; amúkun ko ikogun.