3 Li ariwo irọ́kẹ̀kẹ li awọn enia sá, ni gbigbe ara rẹ soke li a fọ́n awọn orilẹ-ède ká.
4 A o si ṣà ikogun nyin jọ bi ikojọ awọn ẹlẹngà: bi isure siwa, isure sẹhìn awọn eṣú, li on o sure si wọn.
5 Gbigbega li Oluwa; nitori on ngbe ibi giga: on ti fi idajọ ati ododo kún Sioni.
6 On o si jẹ iduroṣinṣin akoko rẹ̀, iṣura igbala, ọgbọ́n ati ìmọ; ìbẹru Oluwa ni yio jẹ iṣura rẹ̀.
7 Kiyesi i, awọn akọni kigbe lode, awọn ikọ̀ alafia sọkún kikorò.
8 Ọ̀na opopo nla wọnni ṣófo, èro dá, on ti bà majẹmu jẹ, o ti kẹgàn ilu wọnni, kò kà ẹnikan si.
9 Ilẹ ngbawẹ̀ o si njoro, oju ntì Lebanoni o si rọ: Ṣaroni dabi aginju; ati Baṣani ati Karmeli gbọ̀n eso wọn danù.